12. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli.
13. Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
14. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’
15. ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba.
16. Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’