Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 16:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà.

9. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e.

10. Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín.

11. Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.

12. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi.

13. “Ọjọ́ meje ni ẹ gbọdọ̀ máa fi se àsè àjọ̀dún àgọ́ nígbà tí ẹ bá kó ọkà yín jọ láti ibi ìpakà, tí ẹ kó ọtí waini yín jọ láti ibi ìfúntí.

14. Ẹ máa yọ̀, bí ẹ ti ń gbádùn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin, ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin ati àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, àwọn ọmọ Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà ní àwọn ìlú yín.

15. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi se àsè yìí fún OLUWA Ọlọrun yín níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun gbogbo èso yín, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo láyọ̀ gidigidi.

16. “Ìgbà mẹta láàrin ọdún kan ni gbogbo àwọn ọkunrin yín yóo máa farahàn níwájú OLUWA níbi tí OLUWA bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun; àkókò àjọ̀dún burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati àkókò àjọ̀dún ìkórè, ati àkókò àjọ̀dún àgọ́. Wọn kò gbọdọ̀ farahàn níwájú OLUWA ní ọwọ́ òfo.

17. Olukuluku ọkunrin yóo mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí ó bá ti fẹ́ ati gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun un.

18. “Ẹ yan àwọn adájọ́ ati àwọn olórí tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà yín, ní àwọn ìlú yín, wọn yóo sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn eniyan.

19. Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju, ẹ kò sì gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀; nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ọlọ́gbọ́n lójú, a sì máa yí ẹjọ́ aláre pada sí ẹ̀bi.

Ka pipe ipin Diutaronomi 16