Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 14:24-29 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá bukun yín tán, tí ibi tí ó yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà jù fun yín láti ru ìdámẹ́wàá ìkórè oko yín lọ,

25. ẹ tà á, kí ẹ sì gba owó rẹ̀ sọ́wọ́, kí ẹ kó owó náà lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

26. Ẹ fi owó náà ra ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́, ìbáà ṣe akọ mààlúù, tabi aguntan, tabi ọtí waini, tabi ọtí líle, tabi ohunkohun tí ọkàn yín bá ṣá fẹ́. Ẹ óo jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ẹ óo sì máa yọ̀, ẹ̀yin ati ìdílé yín.

27. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin yín nítorí pé, wọn kò ní ìpín tabi ohun ìní láàrin yín.

28. Ní òpin ọdún kẹtakẹta, ẹ níláti kó ìdámẹ́wàá ìkórè gbogbo oko yín ti ọdún náà jọ, kí ẹ kó wọn kalẹ̀ ninu gbogbo àwọn ìlú yín.

29. Kí àwọn ọmọ Lefi, tí wọn kò ní ìpín ati ohun ìní láàrin yín, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó tí wọ́n wà ninu àwọn ìlú yín jẹ, kí wọ́n sì yó, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 14