Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 12:18-30 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19. Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín.

20. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.

21. Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.

22. Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

23. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀.

24. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA.

26. Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ.

27. Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀.

28. Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

29. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀;

30. ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’

Ka pipe ipin Diutaronomi 12