Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 12:15-26 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Ṣugbọn ẹ lè pa iye ẹran tí ó bá wù yín, kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbikíbi tí ẹ bá ń gbé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín tó. Ẹni tí ó mọ́, ati ẹni tí kò mọ́ lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

16. Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi.

17. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín.

18. Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19. Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín.

20. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.

21. Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.

22. Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

23. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀.

24. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA.

26. Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ.

Ka pipe ipin Diutaronomi 12