Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 10:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé.

16. Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́.

17. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun àwọn ọlọ́run, ati OLUWA àwọn olúwa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù ni Ọlọrun yín, kì í ṣe ojuṣaaju, kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

18. A máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn aláìníbaba ati àwọn opó. Ó fẹ́ràn àwọn àlejò, a sì máa fún wọn ní oúnjẹ ati aṣọ.

19. Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn àwọn àlejò; nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Ijipti rí.

20. Ẹ bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun yín; ẹ sìn ín, kí ẹ sì súnmọ́ ọn. Orúkọ rẹ̀ ni kí ẹ máa fi búra.

21. Òun ni kí ẹ máa yìn, òun ni Ọlọrun yín, tí ó ṣe nǹkan ńláńlá tí ó bani lẹ́rù wọnyi fun yín, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.

22. Aadọrin péré ni àwọn baba ńlá yín nígbà tí wọn ń lọ sí ilẹ̀ Ijipti; ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

Ka pipe ipin Diutaronomi 10