Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 1:17-24 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’

18. Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín.

19. “Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea.

20. Mo sọ fun yín nígbà náà pé, ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn ará Amori, tí OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa,

21. ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.

22. “Gbogbo yín wá sọ́dọ̀ mi, ẹ sì wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á rán àwọn eniyan lọ ṣiwaju wa, láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè wá jábọ̀ fún wa, kí á lè mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀, ati àwọn ìlú tí ó yẹ kí á wọ̀.’

23. “Ọ̀rọ̀ yín dára lójú mi, mo sì yan ọkunrin mejila láàrin yín, ọkunrin kọ̀ọ̀kan láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

24. Wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè náà, títí tí wọ́n fi dé àfonífojì Eṣikolu, tí wọ́n sì ṣe amí rẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 1