Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 11:20-34 BIBELI MIMỌ (BM)

20. “Ọba mìíràn yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀, yóo sì rán agbowóopá kan kí ó máa gba owó-odè kiri ní gbogbo ìjọba rẹ̀; ní kò pẹ́ kò jìnnà, a óo pa ọba náà, ṣugbọn kò ní jẹ́ ní gbangba tabi lójú ogun.”

21. Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba.

22. Yóo tú àwọn ọmọ ogun ká níwájú rẹ̀, ati ọmọ aládé tí wọn bá dá majẹmu.

23. Yóo máa fi ẹ̀tàn bá àwọn orílẹ̀-èdè dá majẹmu. Yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ó jọba lé lórí kéré.

24. Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni.

25. “Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn.

26. Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú.

27. Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu.

28. Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

29. “Ní àkókò tí a ti pinnu, yóo tún gbógun ti ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn nǹkan kò ní rí bíi ti àkọ́kọ́ fún un;

30. nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í.“Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀.

31. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32. Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́.

33. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n láàrin wọn óo máa la ọpọlọpọ lọ́yẹ, ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀, wọn óo kú ikú idà, a óo dáná sun wọ́n, a óo kó wọn lẹ́rù, a óo sì kó wọn ní ẹrú lọ.

34. Nígbà tí a bá ṣẹgun wọn, wọn yóo rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà, ọpọlọpọ yóo sì faramọ́ wọn pẹlu ẹ̀tàn.

Ka pipe ipin Daniẹli 11