Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 6:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Wọ́n kọ́ ibi mímọ́ kan sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà, inú ibi mímọ́ yìí ni wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA sí.

20. Gígùn ibi mímọ́ ti inú yìí jẹ́ ogún igbọnwọ, ó fẹ̀ ní ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ. Ojúlówó wúrà ni wọ́n fi bo gbogbo ibi mímọ́ náà; wọ́n sì fi pákó igi kedari ṣe pẹpẹ kan sibẹ.

21. Ojúlówó wúrà ni Solomoni fi bo gbogbo inú ilé ìsìn náà, wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n kan, ó fi dábùú ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́ ti inú, ó sì yọ́ wúrà bò ó.

22. Gbogbo inú ilé ìsìn náà patapata ni wọ́n fi wúrà bò, ati pẹpẹ tí ó wà ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ.

23. Wọ́n fi igi olifi gbẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́ meji tí wọn ń pè ní Kerubu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá, wọ́n kó wọn sinu Ibi-Mímọ́-Jùlọ náà.

24. Ìyẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn Kerubu mejeeji gùn ní igbọnwọ marun-un, tí ó fi jẹ́ pé láti ṣóńṣó ìyẹ́ kinni Kerubu kọ̀ọ̀kan dé ṣóńṣo ìyẹ́ rẹ̀ keji jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá.

25. Gígùn ìyẹ́ mejeeji Kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Bákan náà ni àwọn Kerubu mejeeji yìí rí, bákan náà sì ni títóbi wọn.

26. Ekinni keji wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá.

27. Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà.

28. Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 6