Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 21:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Naboti, ará Jesireeli, ní ọgbà àjàrà kan. Ní Jesireeli ni ọgbà yìí wà, lẹ́bàá ààfin Ahabu, ọba Samaria.

2. Ní ọjọ́ kan, Ahabu pe Naboti ó ní, “Fún mi ni ọgbà àjàrà rẹ, mo fẹ́ lo ilẹ̀ náà fún ọgbà ewébẹ̀ nítorí ó súnmọ́ tòsí ààfin mi. N óo fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju èyí lọ dípò rẹ̀, tabi tí ó bá sì wù ọ́, n óo san owó rẹ̀ fún ọ.”

3. Naboti dáhùn pé, “Ọwọ́ àwọn baba ńlá mi ni mo ti jogún ọgbà àjàrà yìí; OLUWA má jẹ́ kí n rí ohun tí n óo fi gbé e fún ọ.”

4. Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 21