Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 15:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ogun tí ó wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu tún wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Abijamu wà lórí oyè.

7. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Abijamu ṣe wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ogun si wà láàrin Abijah ati Jeroboamu.

8. Abijamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi, Asa, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

9. Nígbà tí ó di ogún ọdún tí Jeroboamu ti jọba Israẹli ni Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda.

10. Ọdún mọkanlelogoji ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá baba rẹ̀.

11. Asa ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀.

12. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí wọ́n wà ní ojúbọ àwọn oriṣa káàkiri ní ilẹ̀ Juda, ni Asa lé jáde kúrò ni ilẹ̀ náà; ó sì kó gbogbo àwọn oriṣa tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe dànù.

13. Ó yọ Maaka, ìyá baba rẹ̀, kúrò lórí oyè ìyá ọba, nítorí pé Maaka yá ère tí ó tini lójú kan fún oriṣa Aṣera. Asa gé oriṣa náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún ní àfonífojì Kidironi.

14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò pa gbogbo àwọn ojúbọ oriṣa wọn run, ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

15. Gbogbo àwọn ohun èlò pẹlu wúrà ati fadaka tí baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati àwọn tí òun pàápàá yà sọ́tọ̀, ni ó dá pada sinu ilé OLUWA.

16. Nígbà gbogbo ni Asa ọba Juda, ati Baaṣa, ọba Israẹli ń gbógun ti ara wọn, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà lórí oyè.

17. Baaṣa gbógun ti ilẹ̀ Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi yí Rama po, kí ẹnikẹ́ni má baà rí ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, tabi kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 15