Asa ọba bá kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó kù ninu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA ati ti ààfin ọba jọ, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ sí Benhadadi ọmọ Tabirimoni, ọmọ Hesioni, ọba ilẹ̀ Siria, tí ó wà ní ìlú Damasku. Asa ní kí wọ́n wí fún Benhadadi,