Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 15:17-30 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Baaṣa gbógun ti ilẹ̀ Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi yí Rama po, kí ẹnikẹ́ni má baà rí ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, tabi kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

18. Asa ọba bá kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó kù ninu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA ati ti ààfin ọba jọ, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ sí Benhadadi ọmọ Tabirimoni, ọmọ Hesioni, ọba ilẹ̀ Siria, tí ó wà ní ìlú Damasku. Asa ní kí wọ́n wí fún Benhadadi,

19. pé, “Jẹ́ kí a ní àjọṣepọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe; gba wúrà ati fadaka tí mo fi ranṣẹ sí ọ yìí, kí o dẹ́kun àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu Baaṣa ọba Israẹli, kí ó lè kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ mi.”

20. Benhadadi ọba gba ohun tí Asa wí, ó sì rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ láti lọ gbógun ti àwọn ìlú ńláńlá Israẹli. Wọ́n gba ìlú Ijoni ati Dani, Abeli Beti Maaka, ati gbogbo agbègbè Kineroti, pẹlu gbogbo agbègbè Nafutali.

21. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi tí ó ń mọ yí Rama dúró, ó sì ń gbé Tirisa.

22. Asa ọba bá kéde ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ó ní kí gbogbo eniyan patapata láìku ẹnìkan, lọ kó gbogbo òkúta ati igi ti Baaṣa fi ń mọ odi Rama kúrò ní Rama. Igi ati òkúta náà ni Asa fi mọ odi ìlú Geba tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ati ti ìlú Misipa.

23. Gbogbo nǹkan yòókù tí Asa ọba ṣe, ati àwọn ìwà akin tí ó hù, ati àwọn ìlú tí ó mọ odi yípo, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda, ṣugbọn ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, nǹkankan mú un lẹ́sẹ̀.

24. Asa jáde láyé, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

25. Ní ọdún keji tí Asa jọba ní Juda, ni Nadabu, ọmọ Jeroboamu, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba fún ọdún meji.

26. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ọ̀nà baba rẹ̀, ó sì dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ mú kí Israẹli dá.

27. Baaṣa, ọmọ Ahija, láti inú ẹ̀yà Isakari, ṣọ̀tẹ̀ sí Nadabu, ó sì pa á ní ìlú Gibetoni, ní ilẹ̀ Filistia, nígbà tí Nadabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú náà.

28. Ní ọdún kẹta tí Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda, ni Baaṣa pa Nadabu. Baaṣa gorí oyè dípò Nadabu, ó sì di ọba ilẹ̀ Israẹli.

29. Lẹsẹkẹsẹ tí Baaṣa gorí oyè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìdílé Jeroboamu. Gbogbo ìran Jeroboamu pátá ni Baaṣa pa láìku ẹyọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu iranṣẹ rẹ̀, wolii Ahija, ará Ṣilo.

30. Nítorí Jeroboamu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu: ó dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú kí Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 15