Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 14:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Àwọn ẹ̀yà Juda ṣẹ̀ sí OLUWA, wọ́n sì ṣe ohun tí ó mú un bínú lọpọlọpọ ju gbogbo àwọn baba ńlá wọn lọ.

23. Nítorí wọ́n kọ́ pẹpẹ ìrúbọ, wọ́n sì ri ọ̀wọ̀n òkúta ati ère oriṣa Aṣerimu mọ́lẹ̀ lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ igi tútù káàkiri.

24. Àwọn ọkunrin tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó ní ojúbọ àwọn oriṣa náà sì pọ̀ ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe, ni àwọn náà ń ṣe.

25. Ní ọdún karun-un ìjọba Rehoboamu, Ṣiṣaki, ọba Ijipti, gbógun ti Jerusalẹmu.

26. Ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti ààfin ọba pátá; gbogbo apata wúrà tí Solomoni ṣe ni ó kó lọ pẹlu.

27. Rehoboamu bá ṣe apata idẹ dípò wọn. Ó sì fi àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ààfin ọba ṣe alabojuto wọn.

28. Nígbàkúùgbà tí ọba bá ń lọ sinu ilé OLUWA, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé apata náà tẹ̀lé e, wọn á sì dá wọn pada sinu ilé ìṣúra lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́.

29. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Rehoboamu ọba ṣe ni a kọ sílẹ̀ ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

30. Ní gbogbo ìgbà ayé Rehoboamu ati ti Jeroboamu ni àwọn mejeeji í máa gbógun ti ara wọn.

31. Rehoboamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín sinu ibojì ọba, ní ìlú Dafidi. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Abijamu ọmọ rẹ̀ ni ó sì gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 14