Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 6:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa.

2. Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.”Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.”

3. Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀.

4. Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi.

5. Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!”

6. Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?”Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi.

7. Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà.

8. Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli.

9. Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ.

10. Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà.

11. Ọkàn ọba Siria kò balẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ yìí, nítorí náà, ó pe gbogbo àwọn olórí ogun rẹ̀ jọ, ó sì bi wọ́n pé, “Ta ló ń tú àṣírí wa fún ọba Israẹli ninu yín?”

12. Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 6