Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 3:18-24 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nǹkan kékeré ni èyí jẹ́ níwájú OLUWA, yóo fun yín ní agbára láti borí àwọn ará Moabu.

19. Ẹ óo ṣẹgun àwọn ìlú olódi ati àwọn ìlú dáradára wọn, ẹ óo gé gbogbo igi dáradára, ẹ ó dí gbogbo orísun omi wọn; ẹ óo sì da òkúta sí gbogbo ilẹ̀ oko wọn.”

20. Ní ọjọ́ keji, ní àkókò ìrúbọ òwúrọ̀, omi ya wá láti apá Edomu, títí tí gbogbo ilẹ̀ fi kún fún omi.

21. Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn.

22. Nígbà tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, tí oòrùn ń ràn sórí omi náà, àwọn ará Moabu rí i pé omi tí ó wà níwájú àwọn pọ́n bí ẹ̀jẹ̀.

23. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.”

24. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ibùdó-ogun náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli kọlù wọ́n, títí tí wọ́n fi sá pada; wọ́n sì ń pa wọ́n ní ìpakúpa bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 3