Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 23:3-17 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́.

4. Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli.

5. Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú.

6. Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan.

7. Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera.

8. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú.

9. Kò gba àwọn alufaa náà láàyè láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA, ṣugbọn wọ́n lè jẹ ninu àkàrà tí wọn kò fi ìwúkàrà ṣe, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn.

10. Josaya Ọba wó ilé oriṣa Tofeti tí ó wà ní àfonífojì Hinomu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè fi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ̀ rúbọ sí oriṣa Moleki mọ́.

11. Ó tú gbogbo ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, lẹ́bàá yàrá Natani Meleki, ìwẹ̀fà tí ó wà ní agbègbè ilé OLUWA; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn.

12. Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi.

13. Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni.

14. Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde.

15. Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.

16. Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà,

17. ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?”Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 23