Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 21:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. OLUWA sọ láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, pé,

11. “Manase ọba ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, wọ́n burú ju èyí tí àwọn ará Kenaani ṣe lọ. Ó sì mú kí Juda dẹ́ṣẹ̀ nípa pé wọ́n ń bọ àwọn ère rẹ̀.

12. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ìparun wá sórí Jerusalẹmu ati Juda, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́.

13. Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀.

14. OLUWA ní òun óo kọ àwọn eniyan òun yòókù sílẹ̀, òun óo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn, wọn yóo sì kó wọn lọ bí ìkógun.

15. Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú lójú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.”

16. Manase pa ọpọlọpọ àwọn eniyan aláìṣẹ̀ títí tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn ní ìgboro Jerusalẹmu. Ó tún fa àwọn eniyan Juda sinu ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà; nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

17. Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 21