Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 2:19-24 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20. Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí.

21. Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ sí ibi orísun omi náà, ó da iyọ̀ náà sí i, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA wí, ‘Mo sọ omi yìí di ọ̀tun lónìí, kò ní fa ikú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ba oyún jẹ́ mọ́.’ ”

22. Láti ìgbà náà ni omi náà ti dára títí di òní olónìí gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ.

23. Eliṣa kúrò níbẹ̀, ó lọ sí Bẹtẹli. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọdekunrin kan ní ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí fi Eliṣa ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n ń wí pé, “Kúrò níbí, ìwọ apárí! Kúrò níbí, ìwọ apárí!”

24. Nígbà tí ó yí ojú pada, tí ó rí wọn, ó ṣépè lé wọn ní orúkọ OLUWA, abo ẹranko beari meji sì jáde láti inú igbó, wọ́n fa mejilelogoji ninu àwọn ọmọ náà ya.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 2