Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 2:16-20 BIBELI MIMỌ (BM)

16. wọ́n ní, “Aadọta ọkunrin alágbára wà pẹlu àwa iranṣẹ rẹ, jọ́wọ́ jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ, bóyá Ẹ̀mí OLUWA tí ó gbé e lọ ti jù ú sílẹ̀ ní orí ọ̀kan ninu àwọn òkè agbègbè yìí, tabi ninu àfonífojì kan.”Eliṣa sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe rán wọn lọ.”

17. Ṣugbọn wọ́n rọ̀ ọ́ títí tí ojú fi ń tì í, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n bá rán àwọn aadọta ọkunrin lọ, wọ́n wá Elija ní àwọn orí òkè ati àwọn àfonífojì fún ọjọ́ mẹta, ṣugbọn wọn kò rí i.

18. Wọ́n pada wá jábọ̀ fún Eliṣa ní Jẹriko, ó sì wí fún wọn pé, “Ṣebí mo ti sọ fun yín pé kí ẹ má lọ?”

19. Àwọn ọkunrin ìlú náà wá sọ́dọ̀ Eliṣa, wọ́n sọ fún un pé, “Ìlú yìí dára gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, ṣugbọn omi tí à ń mu kò dára, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”

20. Eliṣa bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bu iyọ̀ sinu abọ́ tuntun, kí ẹ sì gbé e wá fún mi.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 2