Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 2:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí àkókò tó fún OLUWA láti fi ààjà gbé Elija lọ sí ọ̀run, Elija ati Eliṣa kúrò ní Giligali.

2. Elija sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí Bẹtẹli.”Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Bẹtẹli.

3. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Bẹtẹli tọ Eliṣa wá, wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.”

4. Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.”Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko.

5. Àwọn ọmọ wolii tí wọn ń gbé Jẹriko tọ Eliṣa wá, wọ́n sì bi í pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé OLUWA yóo mú ọ̀gá rẹ lọ lónìí?”Eliṣa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀, ṣugbọn ẹ má ṣe sọ ohunkohun nípa rẹ̀.”

6. Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín nítorí pé OLUWA rán mi sí odò Jọdani.”Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ ń lọ.

7. Aadọta ninu àwọn ọmọ àwọn wolii náà sì dúró ní òkèèrè, wọ́n ń wò wọ́n. Elija ati Eliṣa sì dúró létí odò Jọdani.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 2