Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 19:21-36 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’

22. Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń kígbe mọ́,tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni!

23. O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

24. Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,mo sì mu omi rẹ̀;ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’

25. “Ṣé o kò mọ̀ péó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni?Èmi ni mo fún ọ ní agbáratí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà.

26. Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára,tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùnbá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé.

27. Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ,mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí.

28. Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.”

29. Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.

30. Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde.

31. Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é.

32. “Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í.

33. Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

34. N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.”

35. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́.

36. Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 19