Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 19:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.”

20. Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria.

21. Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’

22. Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń kígbe mọ́,tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni!

23. O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

24. Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,mo sì mu omi rẹ̀;ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’

25. “Ṣé o kò mọ̀ péó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni?Èmi ni mo fún ọ ní agbáratí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà.

26. Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára,tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùnbá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé.

27. Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ,mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí.

28. Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.”

29. Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.

30. Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde.

31. Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 19