Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 18:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kẹta tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba ní Israẹli ni Hesekaya, ọmọ Ahasi jọba ní Juda.

2. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀.

4. Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i.

5. Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀.

6. Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́.

7. OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́.

8. Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn.

9. Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 18