Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 17:32-41 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Àwọn eniyan náà bẹ̀rù OLUWA pẹlu, wọ́n sì yan oniruuru eniyan lára wọn, láti máa ṣe alufaa níbi àwọn pẹpẹ oriṣa gíga, láti máa bá wọn rúbọ níbẹ̀.

33. Wọ́n ń sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n tún ń bọ àwọn oriṣa tí wọn ń bọ tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí olukuluku wọ́n ti wá.

34. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe títí di òní olónìí. Wọn kò bẹ̀rù OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, tabi àṣẹ tí ó pa, tabi òfin tí ó ṣe fún àwọn ọmọ Jakọbu, tí ó sọ ní Israẹli.

35. OLUWA bá wọn dá majẹmu, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, wọn kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, tabi kí wọ́n júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tabi kí wọ́n rúbọ sí wọn;

36. ṣugbọn wọ́n gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti pẹlu ọwọ́ agbára ńlá ati ipá. Ó ní kí wọ́n máa tẹríba fún un, kí wọn sì máa rúbọ sí i.

37. Ó ní wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, àṣẹ ati òfin tí ó kọ sílẹ̀ fún wọn mọ́. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa,

38. wọn kò sì gbọdọ̀ gbàgbé majẹmu tí òun bá wọn dá. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa,

39. ṣugbọn kí wọn bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wọn, yóo sì gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn.

40. Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò gbọ́, wọ́n sì ń tẹ̀lé ìwà àtijọ́ wọn.

41. Àwọn eniyan ilẹ̀ náà sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n ń bọ àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ pẹlu. Àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 17