Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 11:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní kété tí Atalaya, ìyá ọba Ahasaya gbọ́ nípa ikú ọmọ rẹ̀, ó pa gbogbo ìdílé ọba run.

2. Joaṣi ọmọ Ahasaya nìkan ni kò pa nítorí pé Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasaya, gbé e sá lọ; ó sì fi òun ati alágbàtọ́ rẹ̀ pamọ́ sí yàrá kan ninu ilé OLUWA, kí Atalaya má baà pa á. Ó gbé e pamọ́ fún Atalaya, Atalaya kò sì rí i pa.

3. Joaṣi wà ní ìpamọ́ ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa, Atalaya sì ń jọba lórí ilẹ̀ Juda.

4. Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n.

5. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 11