Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 9:44-57 BIBELI MIMỌ (BM)

44. Abimeleki ati àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sáré, wọ́n lọ gba ẹnu ọ̀nà bodè ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun meji yòókù sáré sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu pápá, wọ́n pa wọ́n.

45. Abimeleki gbógun ti ìlú náà ní gbogbo ọjọ́ náà, ó gbà á, ó sì pa àwọn eniyan inú rẹ̀; ó wó gbogbo ìlú náà palẹ̀, ó sì da iyọ̀ sí i.

46. Nígbà tí gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu gbọ́, wọ́n sá lọ sí ibi ààbò tí ó wà ní ilé Eli-beriti.

47. Wọ́n sọ fún Abimeleki pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ tí ó wà ní Ṣekemu ti kó ara wọn jọ sí ibìkan.

48. Abimeleki bá lọ sí òkè Salimoni, òun ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó mú àáké kan lọ́wọ́, ó fi gé ẹrù igi kan jọ, ó gbé e lé èjìká, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pé, “Ẹ yára ṣe bí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.”

49. Olukuluku wọn náà bá gé ẹrù igi kọ̀ọ̀kan, wọ́n tẹ̀lé Abimeleki. Wọ́n to ẹrù igi wọn jọ sí ara ibi ààbò náà, wọn sọ iná sí i. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé ìṣọ́ Ṣekemu sì kú patapata. Wọ́n tó ẹgbẹrun (1,000) eniyan, atọkunrin, atobinrin.

50. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó gbógun tì í, ó sì gbà á.

51. Ṣugbọn ilé ìṣọ́ kan tí ó lágbára wà ninu ìlú náà, gbogbo àwọn ará ìlú sá lọ sinu rẹ̀, atọkunrin, atobinrin. Wọ́n ti ara wọn mọ́ inú rẹ̀, wọ́n sì gun òkè ilé ìṣọ́ náà lọ.

52. Nígbà tí Abimeleki dé ibi ilé ìṣọ́ náà, ó gbógun tì í. Ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún.

53. Obinrin kan bá gbé ọmọ ọlọ kan, ó sọ ọ́ sílẹ̀, ọmọ ọlọ yìí bá Abimeleki lórí, ó sì fọ́ agbárí rẹ̀.

54. Ó yára pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó wí fún un pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn eniyan má baà máa wí pé, ‘Obinrin kan ni ó pa á.’ ” Ọdọmọkunrin yìí bá gún un ní idà, ó sì kú.

55. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Abimeleki ti kú, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.

56. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbẹ̀san lára Abimeleki fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ baba rẹ̀, nítorí pé, ó pa aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀.

57. Ọlọrun sì mú kí gbogbo ìwà ibi àwọn ará Ṣekemu pada sórí wọn. Èpè tí Jotamu ọmọ Gideoni ṣẹ́ sì ṣẹ mọ́ wọn lára.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 9