Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 6:26-40 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.”

27. Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.

28. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́.

29. Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”

30. Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

31. Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.”

32. Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.

33. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli.

34. Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e.

35. Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀.

36. Gideoni wí fún Ọlọrun pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí,

37. n óo fi irun aguntan lélẹ̀ ní ibi ìpakà, bí ìrì bà sẹ̀ sórí irun yìí nìkan, tí gbogbo ilẹ̀ tí ó yí i ká bá gbẹ, nígbà náà ni n óo gbà pé nítòótọ́, èmi ni o fẹ́ lò láti gba Israẹli kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti wí.”

38. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó jí ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, tí ó sì fún irun aguntan náà, ìrì tí ó fún ní ara rẹ̀ kún abọ́ kan.

39. Gideoni tún wí fún Ọlọrun pé, “Jọ̀wọ́, má jẹ́ kí inú bí ọ sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ni ó kù tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀; jọ̀wọ́ jẹ́ kí n tún dán kinní kan wò pẹlu irun aguntan yìí lẹ́ẹ̀kan sí i, jẹ́ kí gbogbo irun yìí gbẹ ṣugbọn kí ìrì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀, kí ó sì tutù.”

40. Ọlọrun tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, nítorí pé, orí irun yìí nìkan ṣoṣo ni ó gbẹ, ìrì sì sẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 6