Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 4:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA lẹ́yìn ikú Ehudu.

2. OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀.

3. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́, nítorí pé ẹẹdẹgbẹrun (900) ni kẹ̀kẹ́ ogun Jabini tí wọ́n fi irin ṣe; ó sì ni wọ́n lára fún ogún ọdún.

4. Wolii obinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debora aya Lapidotu, ni adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli nígbà náà.

5. Lábẹ́ ọ̀pẹ kan, tí wọ́n sọ ní ọ̀pẹ Debora, tí ó wà láàrin Rama ati Bẹtẹli ní agbègbè olókè ti Efuraimu ní í máa ń jókòó sí, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli tií máa ń lọ bá a fún ìdájọ́.

6. Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ.

7. N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”

8. Baraki bá dá a lóhùn pé, “Bí o óo bá bá mi lọ ni n óo lọ, bí o kò bá ní bá mi lọ, n kò ní lọ.”

9. Debora dáhùn pé, “Láìṣe àní àní, n óo bá ọ lọ. Ṣugbọn ṣá o, ohun tí o fẹ́ ṣe yìí kò ní já sí ògo fún ọ, nítorí pé, OLUWA yóo fi Sisera lé obinrin kan lọ́wọ́.” Debora bá gbéra, ó bá Baraki lọ sí Kedeṣi.

10. Baraki bá pe àwọn ọmọ Sebuluni ati Nafutali sí Kedeṣi; ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ninu wọn ni wọ́n tẹ̀lé Baraki, Debora náà sì bá wọn lọ.

11. Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu.

12. Nígbà tí Sisera gbọ́ pé Baraki ti lọ sí orí òkè Tabori,

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 4