Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 3:20-31 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí.

21. Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn.

22. Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde.

23. Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà.

24. Lẹ́yìn tí ó ti sá lọ ni àwọn iranṣẹ ọba pada dé. Nígbà tí wọn rí i pé wọ́n ti fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà, wọ́n rò ninu ara wọn pé, bóyá ọba wà ninu ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó wà ninu yàrá orí òrùlé náà ni.

25. Wọ́n dúró títí tí agara fi dá wọn. Ṣugbọn nígbà tí ó kọ̀ tí kò ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n bá mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn; wọ́n bá bá òkú oluwa wọn nílẹ̀.

26. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn iranṣẹ wọnyi ń dúró pé kí ọba ṣílẹ̀kùn, Ehudu ti sá lọ, ó sì ti kọjá òkúta gbígbẹ́ tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó ti sá dé Seira.

27. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọn fèrè ní agbègbè olókè Efuraimu. Àwọn ọmọ Israẹli bá tẹ̀lé e lẹ́yìn láti agbègbè olókè, ó sì ṣiwaju wọn.

28. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.

29. Wọ́n pa àwọn alágbára ati akikanju bí ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ará Moabu, kò sì sí ẹnìkan tí ó là ninu wọn.

30. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe ṣẹgun wọn ní ọjọ́ náà, ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ọgọrin ọdún.

31. Aṣiwaju tí ó tún dìde lẹ́yìn Ehudu ni Ṣamgari, ọmọ Anati, ẹni tí ó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da mààlúù pa ẹgbẹta (600) ninu àwọn ará Filistia; òun náà gba Israẹli kalẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 3