Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 19:17-28 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Bí ó ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn àlejò náà ní ìta gbangba láàrin ìgboro ìlú náà; ó sì bi wọ́n léèrè pé, “Níbo ni ẹ̀ ń lọ, níbo ni ẹ sì ti ń bọ̀?”

18. Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni a ti ń bọ̀, a sì ń lọ sí ìgbèríko kan ní òpin agbègbè olókè Efuraimu níbi tí mo ti wá. Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni mo lọ, mo wá ń pada lọ sílé, nígbà tí a ti dé ìhín, kò sí ẹni tí ó gbà wá sílé.

19. Koríko tí a mú lọ́wọ́ tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa, oúnjẹ ati waini tí a sì mú lọ́wọ́ tó fún èmi ati iranṣẹbinrin rẹ ati ọdọmọkunrin tí ó wà pẹlu wa, ìyà ohunkohun kò jẹ wá.”

20. Baba arúgbó náà bá dáhùn pé, “Ṣé alaafia ni ẹ dé? Ẹ kálọ, n óo pèsè ohun gbogbo tí ẹ nílò fun yín, ẹ ṣá má sun ìta gbangba níhìn-ín.”

21. Baba náà bá mú wọn lọ sí ilé rẹ̀, ó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ní koríko. Wọ́n ṣan ẹsẹ̀ wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.

22. Bí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn lọ́wọ́ ni àwọn ọkunrin lásánlàsàn kan aláìníláárí, ará ìlú náà, bá yí gbogbo ilé náà po, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlẹ̀kùn. Wọ́n sọ fún baba arúgbó tí ó ni ilé náà pé, “Mú ọkunrin tí ó wọ̀ sinu ilé rẹ jáde, kí á lè bá a lòpọ̀.”

23. Baba arúgbó tí ó ni ilé yìí bá jáde sí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wọ́n, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú báyìí, ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí wá wọ̀ sinu ilé mi ni, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí sí i.

24. Mo ní ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ wundia, ọkunrin náà sì ní obinrin kan, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde sí yín nisinsinyii, kí ẹ sì ṣe wọ́n bí ẹ bá ti fẹ́, kí ẹ tẹ́ ìfẹ́ yín lọ́rùn lára wọn, ṣugbọn ẹ má ṣe hu irú ìwà burúkú yìí sí ọkunrin náà.”

25. Ṣugbọn àwọn ọkunrin náà kọ̀, wọn kò dá a lóhùn. Ó bá ki obinrin ọkunrin náà mọ́lẹ̀, ó tì í sí wọn lóde. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lòpọ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, wọ́n fi sílẹ̀ pé kí ó máa lọ.

26. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obinrin yìí bá lọ wó lulẹ̀ sì ẹnu ọ̀nà baba arúgbó náà níbi tí ọkunrin tí ó mú un wá wà, ó wà níbẹ̀ títí tí ilẹ̀ fi mọ́ kedere.

27. Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn.

28. Ó pè é pé kí ó dìde kí àwọn máa lọ. Ṣugbọn obinrin yìí kò dá a lóhùn. Ó bá gbé òkú rẹ̀ nílẹ̀, ó gbé e sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sílé rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 19