Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 11:2-18 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.”

3. Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri.

4. Nígbà tí ó yá, àwọn ará Amoni gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

5. Nígbà tí ogun yìí bẹ̀rẹ̀, àwọn àgbààgbà Gileadi lọ mú Jẹfuta wá láti ilẹ̀ Tobu.

6. Wọ́n bẹ Jẹfuta, wọ́n ní, “A fẹ́ lọ gbógun ti àwọn ará Amoni, ìwọ ni a sì fẹ́ kí o jẹ́ balogun wa.”

7. Ṣugbọn Jẹfuta dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ̀yin ni ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ fi lé mi jáde kúrò ní ilé baba mi? Kí ló dé tí ẹ fi wá sọ́dọ̀ mi nígbà tí ìyọnu dé ba yín?”

8. Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.”

9. Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?”

10. Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “OLUWA ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa pẹlu rẹ pé, ohun tí o bá wí ni a óo ṣe.”

11. Jẹfuta bá àwọn àgbààgbà Gileadi pada lọ, àwọn ará Gileadi sì fi jẹ balogun wọn. Ó lọ siwaju OLUWA ní Misipa, ó sì sọ àdéhùn tí ó bá àwọn àgbààgbà Gileadi ṣe.

12. Lẹ́yìn náà, Jẹfuta ranṣẹ sí ọba àwọn ará Amoni pé, “Kí ni mo ṣe tí o fi gbógun ti ilẹ̀ mi.”

13. Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.”

14. Jẹfuta tún ranṣẹ pada sí ọba Amoni pé,

15. “Gbọ́ ohun tí èmi Jẹfuta wí, Israẹli kò gba ilẹ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn ará Moabu tabi lọ́wọ́ àwọn ará Amoni.

16. Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi.

17. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi.

18. Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 11