Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.”