Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 10:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀.

2. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri.

3. Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun.

4. Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi.

5. Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni.

6. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́.

7. Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́.

8. Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

9. Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 10