Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 5:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ẹni tí ó dá àwọn ìràwọ̀ Pileiadesi ati Orioni,tí ó sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,òun níí sọ ọ̀sán di òru;òun ni ó dá omi òkun sórí ilẹ̀,OLUWA ni orúkọ rẹ̀.

9. Òun ni ó ń mú ìparun wá sórí àwọn alágbára,kí ìparun lè bá ibi ààbò wọn.

10. Wọ́n kórìíra ẹni tí ń bá ni wí lẹ́nu ibodè, wọ́n sì kórìíra ẹni tí ń sọ òtítọ́.

11. Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀.

12. Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè.

Ka pipe ipin Amosi 5