Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 5:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ẹ kórìíra ibi, kí ẹ sì fẹ́ ire, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ lẹ́nu ibodè yín; bóyá OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo ṣàánú fún àwọn ọmọ ilé Josẹfu yòókù.

16. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, àní OLUWA ní: “Ẹkún yóo wà ní gbogbo ìta gbangba, wọn yóo sì máa kọ ‘Háà! Háà!’ nígboro. Wọn yóo pe àwọn àgbẹ̀ pàápàá, ati àwọn tí wọn ń fi ẹkún sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, láti wá sọkún àwọn tí wọ́n kú.

17. Wọn yóo sọkún ninu gbogbo ọgbà àjàrà yín, nítorí pé n óo gba ààrin yín kọjá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

18. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń retí ọjọ́ OLUWA, ẹ gbé! Kí ni ẹ fẹ́ fi ọjọ́ OLUWA ṣe? Ọjọ́ òkùnkùn ni, kì í ṣe ọjọ́ ìmọ́lẹ̀.

19. Yóo dàbí ìgbà tí eniyan ń sálọ fún kinniun, tí ó pàdé ẹranko beari lọ́nà; tabi tí ó sá wọ ilé rẹ̀, tí ó fọwọ́ ti ògiri, tí ejò tún bù ú jẹ.

20. Ṣebí òkùnkùn ni ọjọ́ OLUWA, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀! Ọjọ́ ìṣúdudu láìsí ìmọ́lẹ̀ ni.

21. Ọlọrun ní, “Mo kórìíra ọjọ́ àsè yín, n kò sì ní inú dídùn sí àwọn àpéjọ yín.

22. Bí ẹ tilẹ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ yín sí mi, n kò ní gbà wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní fojú rere wo ẹran àbọ́pa tí ẹ mú wá bí ọrẹ ẹbọ alaafia.

23. Ẹ dákẹ́ ariwo orin yín; n kò fẹ́ gbọ́ ohùn orin hapu yín mọ́.

24. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣàn bí omi, kí òdodo sì máa ṣàn bí odò tí kò lè gbẹ.

25. “Ẹ gbọ́, ilé Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ ati ọrẹ wá fún mi ní gbogbo ogoji ọdún tí ẹ fi wà ninu aṣálẹ̀?

26. Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń sin ère Sakuti, ọba yín, ati Kaiwani, oriṣa ìràwọ̀ yín, ati àwọn ère tí ẹ ṣe fún ara yín.

27. Nítorí náà, n óo ko yín lọ sí ìgbèkùn níwájú Damasku.” OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọrun àwọn Ọmọ Ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Amosi 5