Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 4:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.

7. N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ.

8. Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. “Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.

10. “Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.

11. Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.

12. Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!”

13. Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́,tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan,Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru,tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé;OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!

Ka pipe ipin Amosi 4