Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 62:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí Sioni, ń kò ní dákẹ́,nítorí Jerusalẹmu, ń kò ní sinmi,títí ìdáláre rẹ̀ yóo fi yọ bí ìmọ́lẹ̀,tí ìgbàlà rẹ̀ yóo sì tàn bí àtùpà.

2. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí ìdáláre rẹ,gbogbo ọba ni yóo rí ògo rẹ;orúkọ tuntun, tí OLUWA fúnra rẹ̀ yóo sọ ọ́,ni a óo máa pè ọ́.

3. O óo jẹ́ adé ẹwà lọ́wọ́ OLUWA,ati fìlà oyè lọ́wọ́ Ọlọrun rẹ.

4. A kò ní pè ọ́ ní “Ẹni-tí-a-kọ̀-sílẹ̀” mọ́,bẹ́ẹ̀ ni a kò ní pe ilẹ̀ rẹ ní “Ahoro” mọ́,“Ẹni-OLUWA-fẹ́” ni a óo máa pè ọ́,a óo máa pe ilẹ̀ rẹ ní “Ẹni-a-gbé-níyàwó.”Nítorí pé OLUWA nífẹ̀ẹ́ rẹ,ilẹ̀ rẹ yóo sì dàbí iyawo lójú rẹ̀.

5. Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.

Ka pipe ipin Aisaya 62