Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 57:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,o kó ọpọlọpọ turari lọ,o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10. Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”Ò ń wá agbára kún agbára,nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11. Ta ni ń já ọ láyà,tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,ni o kò fi bẹ̀rù mi?

12. N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13. Nígbà tí o bá kígbe,kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́.Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọAfẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ.Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí,ni yóo ni ilẹ̀ náà,òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.

14. OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe,ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15. Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ,ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́:òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́,ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀.Láti sọ ọkàn wọn jí.

16. Nítorí n kò ní máa jà títí ayé,tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo:nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde,Èmi ni mo dá èémí ìyè.

17. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi,mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi;sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.

18. Mo ti rí bí ó ti ń ṣe,ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn;n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu,n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.

19. Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè,ati àwọn tí ó wà nítòsí;n óo sì wò wọ́n sàn.

Ka pipe ipin Aisaya 57