Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 56:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí OLUWA ní,“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

5. n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.

6. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

7. n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”

8. OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”

9. Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀,gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.

10. Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹligbogbo wọn kò mọ nǹkankan.Ajá tí ó yadi ni wọ́n,wọn kò lè gbó;oorun ni wọ́n fẹ́ràn.Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.

11. Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì,wọn kì í yó.Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan.Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn,olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.

12. Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini,ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó,bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”

Ka pipe ipin Aisaya 56