Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 55:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA ní,“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín,

9. Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,tí èrò mi sì ga ju èrò yín.

10. “Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run,tí wọn kì í pada sibẹ mọ́,ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀,tí ń mú kí nǹkan hù jáde;kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn,kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ.

11. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí,kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe,yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.

12. “Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni,alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà,òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín.Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́,

13. igi Sipirẹsi ni yóo máa hù dípò igi ẹlẹ́gùn-ún,igi Mitili ni yóo sì máa hù dípò ẹ̀gún ọ̀gàn,yóo jẹ́ àmì ìrántí fún OLUWA,ati àpẹẹrẹ ayérayé tí a kò ní parẹ́.”

Ka pipe ipin Aisaya 55