Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 55:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan,olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.

5. O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí,àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ,ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.”

6. Ẹ wá OLUWA nígbà tí ẹ lè rí i,ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7. Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀,kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀,kí ó yipada sí OLUWA,kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀.Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa,nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ.

8. OLUWA ní,“Nítorí èrò tèmi yàtọ̀ sí tiyín,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi yàtọ̀ sí tiyín,

Ka pipe ipin Aisaya 55