Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 55:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní,“Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà;bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́,ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ.Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́,kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé.

2. Kí ló dé tí ẹ̀ ń ná owó yín lórí ohun tí kì í ṣe oúnjẹ?Tí ẹ sì ń ṣe làálàá lórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára,kí ẹ sì jẹ ohun tí ó dára,ẹ jẹ oúnjẹ aládùn, kí inú yín ó dùn.

3. “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi,ẹ gbọ́ ohun tí mò ń wí kí ẹ lè yè.N óo ba yín dá majẹmu ayérayé,ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún Dafidi.

4. Wò ó! Mo fi í ṣe olórí fún àwọn eniyan,olórí ati aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.

5. O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí,àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ,ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.”

Ka pipe ipin Aisaya 55