Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,ó ti yanu kalẹ̀.Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.

15. A tẹ eniyan lórí ba,a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀.

16. Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogunni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodoỌlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo.

17. Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọnàwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.

18. Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.

19. Tí wọn ń wí pé:“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”

20. Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;tí wọn ń pe ire ní ibi!Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò.

21. Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!

22. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;tí wọ́n jẹ́ akikanjubí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn!

23. Àwọn tí wọn ń dá ẹni tí ó jẹ̀bi sílẹ̀nígbà tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tán;tí wọn kì í jẹ́ kí aláìṣẹ̀ rí ẹ̀tọ́ gbà.

24. Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,tíí sìí jó ewéko ní àjórun;bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.

25. Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀,ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n,àwọn òkè sì mì tìtì.Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro,sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.

Ka pipe ipin Aisaya 5