Nítorí náà, bí iná tíí jó àgékù igi kanlẹ̀,tíí sìí jó ewéko ní àjórun;bẹ́ẹ̀ ní gbòǹgbò wọn yóo ṣe rà,tí ìtànná wọn yóo sì fẹ́ lọ bí eruku.Nítorí wọ́n kọ òfin OLUWA àwọn ọmọ ogun sílẹ̀,wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli.