Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 48:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.

7. Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.Kí ẹ má baà wí pé:Wò ó, a mọ̀ wọ́n.

8. Ẹ kò gbọ́ ọ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.

9. “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,kí n má baà pa yín run.

10. Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.

11. Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi ni mo ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.Nítorí kí ni ìdí rẹ̀ tí orúkọ mi yóo ṣe díbàjẹ́,n kò ní gbé ògo mi fún ẹlòmíràn.

12. “Tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ìwọ Jakọbu,ìwọ Israẹli, ẹni tí mo pè,Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀,èmi sì ni ẹni òpin.

13. Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo fi ta awọsanma sójú ọ̀run.Nígbà tí mo pè wọ́n, gbogbo wọn jọ yọ síta.

14. “Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́,èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi?OLUWA fẹ́ràn rẹ̀,yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni,yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.

15. Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é,èmi ni mo mú un wá,yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 48