Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 48:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè,ọmọ bíbí inú Juda,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra,tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli,ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.

2. Ẹ̀ ń pe ara yín ní ará ìlú mímọ́,ẹ fẹ̀yìn ti Ọlọrun Israẹli,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.

3. OLUWA ní, “Láti ìgbà àtijọ́ ni mo ti kéde,àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,èmi ni mo sọ wọ́n jáde,tí mo sì fi wọ́n hàn.Lójijì mo ṣe wọ́n,nǹkan tí mo sọ sì ṣẹ.

4. Nítorí mo mọ̀ pé alágídí ni yín,olóríkunkun sì ni yín pẹlu.

5. Mo ti sọ fun yín láti ọjọ́ pípẹ́:kí wọn tó ṣẹlẹ̀, mo ti kéde wọn fun yín,kí ẹ má baà sọ pé, ‘oriṣa wa ni ó ṣe wọ́n,àwọn ère wa ni ó pàṣẹ pé kí wọn ṣẹlẹ̀.’

6. “Ẹ ti fetí ara yín gbọ́,nítorí náà, ẹ wo gbogbo èyí, ṣé ẹ kò ní kéde rẹ̀?Láti àkókò yìí lọ, n óo mú kí ẹ máa gbọ́ nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farapamọ́ tí ẹ kò mọ̀.

7. Kò tíì pẹ́ tí a dá wọn,ẹ kò gbọ́ nípa wọn rí, àfi òní.Kí ẹ má baà wí pé:Wò ó, a mọ̀ wọ́n.

8. Ẹ kò gbọ́ ọ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.Ọjọ́ ti pẹ́ tí a ti di yín létí,nítorí mo mọ̀ pé ẹ óo hùwà àgàbàgebè,ọlọ̀tẹ̀ ni orúkọ tí mo mọ̀ yín mọ̀,láti ìgbà tí ẹ ti jáde ninu oyún.

9. “Mo dáwọ́ ibinu mi dúró ná, nítorí orúkọ mi,nítorí ìyìn mi ni mo ṣe dá a dúró fun yín,kí n má baà pa yín run.

10. Mo ti fọ̀ ọ́ mọ́,ṣugbọn kì í ṣe bí a tií fọ fadaka,mo dán yín wò ninu iná ìpọ́njú.

Ka pipe ipin Aisaya 48