Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 45:4-20 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi,ati Israẹli, àyànfẹ́ mi,mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ.Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí.

5. “Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn,kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí.

6. Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn.

7. Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn,èmi ni mo dá alaafia ati àjálù:Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.

8. Rọ òjò sílẹ̀, ìwọ ọ̀run,kí ojú ọ̀run rọ̀jò òdodo sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ lanu, kí ìgbàlà lè yọ jáde.Jẹ́ kí ó mú kí òdodo yọ jáde pẹlu,èmi OLUWA ni mo ṣẹ̀dá rẹ̀ bẹ́ẹ̀.

9. “Ẹni tí ń bá ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà gbé!Ìkòkò tí ń bá amọ̀kòkò jà.Ṣé amọ̀ lè bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ń mọ ọ́n pé:‘Kí ni ò ń mọ?’Tabi kí ó sọ fún un pé,‘Nǹkan tí ò ń mọ kò ní ìgbámú?’

10. Ẹnìkan lè bi baba rẹ̀ pé:‘Irú kí ni o bí?’Tabi kí ó bi ìyá rẹ̀ léèrè pé:‘Irú ọmọ wo ni o bí yìí?’Olúwarẹ̀ gbé!”

11. OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ẹlẹ́dàá rẹ ni,“Ṣé ẹ óo máa bi mí ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ mi ni,tabi ẹ óo máa pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi?

12. Èmi ni mo dá ayé,tí mo dá eniyan sórí rẹ̀.Ọwọ́ mi ni mo fi ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí mo sì pàṣẹ fún oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀.

13. Èmi ni mo gbé Kirusi dìde ninu òdodo mi,n óo mú kí ó ṣe nǹkan bí ó ti tọ́;òun ni yóo tún ìlú mi kọ́,yóo sì dá àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní ìgbèkùn sílẹ̀,láìgba owó ati láìwá èrè kan.”OLUWA àwọn ọmọ ogun ló sọ bẹ́ẹ̀.

14. Ó ní, “Àwọn ọrọ̀ ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ẹrù ilẹ̀ Etiopia,ati àwọn ọkunrin Seba tí wọn ṣígbọnlẹ̀,wọn óo tọ̀ ọ́ wá, wọn óo di tìrẹ,wọn óo sì máa tẹ̀lé ọ.Wọn óo wá, pẹlu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lẹ́sẹ̀ wọn,wọn óo sì wólẹ̀ fún ọ.Wọn óo máa bẹ̀ ọ́ pé,‘Lọ́dọ̀ rẹ nìkan ni Ọlọrun wà,kò tún sí Ọlọrun mìíràn.Kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ.’ ”

15. Nítòótọ́,ìwọ ni Ọlọrun tí ó ń fi ara pamọ́,Ọlọrun Israẹli, Olùgbàlà.

16. Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì,ìdààmú yóo sì bá wọn.Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ èreyóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.

17. Ṣugbọn OLUWA gba Israẹli là,títí ayé sì ni ìgbàlà rẹ̀.Ojú kò ní tì ọ́, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní dààmú, títí lae.

18. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.)Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀,kò dá a ninu rúdurùdu,ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.

19. N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”

20. OLUWA ní:“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,ẹ jọ súnmọ́ bí,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,tí wọ́n sì ń gbadurasí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.

Ka pipe ipin Aisaya 45