Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 44:2-19 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.

3. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹn óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,

4. wọn óo rúwé bíi koríko inú omiàní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.

5. “Ẹnìkan yóo wí pé,‘OLUWA ló ni mí.’Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”

6. Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.

7. Ta ni ó dàbí mi? Kí olúwarẹ̀ sọ̀rọ̀kí ó kéde rẹ̀ níwájú mi.Ẹni tí ó bá ti kéde láti ìbẹ̀rẹ̀, nípa àwọn nǹkan tí yóo ṣẹlẹ̀,kí wọn sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa.

8. Má bẹ̀rù, má sì fòyà.Ṣebí mo ti sọ fún ọ tipẹ́,mo ti kéde rẹ̀,ìwọ sì ni ẹlẹ́rìí mi:Ǹjẹ́ Ọlọrun mìíràn wà lẹ́yìn mi?Kò tún sí àpáta kan mọ́, n kò mọ ọ̀kan kan.”

9. Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n.

10. Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè?

11. Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀.

12. Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.

13. Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un.

14. Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà.

15. Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un.

16. Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.”

17. Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”

18. Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.

19. Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”

Ka pipe ipin Aisaya 44