Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 43:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu,gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí,Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ.Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada;mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.

2. Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá,n óo wà pẹlu rẹ;nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá,kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀,nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ.Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.

3. Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ.Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada,mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.

4. Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.

5. Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.

6. N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé,‘Dá wọn sílẹ̀.’N óo sọ fún ìhà gúsù pé,‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè,sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé,

7. gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè,àwọn tí mo dá fún ògo mi,àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”

8. Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde,àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́,wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.

9. Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ,kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀.Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí,tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá;kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́,kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”

10. OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.

11. “Èmi ni OLUWA,kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.

12. Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là,mo sì ti kéde,nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín;ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13. Èmi ni Ọlọrun,láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni.Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi:Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”

14. OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.

15. Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”

16. OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;

Ka pipe ipin Aisaya 43